Ijapa ati aguntan lati owo Alphonso Olasumbo (yoruba version of the tortoise and the sheep)

 

     Ni igba kan ri,ni ilu agbariko awon eranko.ijapa so ara re did or apapandodo pelu aguntan omo jeje ati eranko onirele.
     Ijapa eniti gbogbogbo aye ti mo si ole,ati alarekereke a ma fi gbobgo igba wa eniti Yi o lo fun iwa imotara enikan re.
     Ni ojo kan,leyin igba ti aguntan to fi okan tan ijapa, ijapa so fun aguntan pe opolopo ounje wa fun won lati ko ninu igbo opoounje eyiti opolopo eranko ko i ti mo nipa re nilu agbariko. Inu aguntan dun pupo nitori iyan kekere kan nmu lowo nilu naa.
     Ijapa so fun aguntan pe apo kan ni awon mejeji you mu lowo lo ti won o fi ko opolopo eso aladun wale eyiti won o pin dogba nigba ti won ba dele tan. inu aguntan dun pupo to bee gee ti o fi gba lati ba ijapa lo.
    Ni ojo Keji,awon mejeji Kori si ona igbo opoounje pelu sago omi nla kan ti ijapa so fun aguntan pe oun ni won yio lo lati gbemiro de igbo opoounje. ijapa wa bere si ni mu omi ni iseju iseju ti o fi mu gbogbo omi ti won gbe dani tan ki won to de igbo opoounje.
    Laipe won de igbo opoounje,won si ba opolopo eso gege bi ijapa ti so tele. won bere sini ko eso sinu apo,sugbon ki won o to sise die, ijapa gba inu mu o si so fun aguntan pe o di dandan ki oun lo wa ibi ti see igbonse. Bayi ni ijapa dogbon yera titi  aguntan fi nikan see gbogbo ise. laimo pe bi a ti gbon nile oko be laa gbon nile ale. Aguntan ti mu iru apo ti won mu dani, o si ko opolopo eso ti o ti baje ati okuta sinu re. O gbe apo ti eso re dara pamo o si see ojure wai, o si duro de ijapa lati pada wa.
      Laipe ijapa de,o si ran aguntan ni ise egoo lati lo pon omi wa nitori ati fi gbemiro ni irin ajo won pada si ilu agbariko.o kilo fun aguntan ki o ma se pon omi naa ni odo to o wa nitosi nitori odo orisanla aseda ni odo naa.
       Aguntan fi tirele tirele lo pon omi naa. Nigbati ijapa ri pe o ti rin jinna, ti o si woye pe auntan ko le gbo oun mo, o rora fa apo eso kuro nibi ti aguntan gbe si, o sii gbe pamo, o si fi suuru duro de aguntan. Bi ose bere si ni gbo iro ese aguntan nitosi lori awon ewe gbigbe,loba fi gbe taa, lo bere sini Sanra mole.
       Aguntan sare si i, o beere lowo re pe e”ore mi,kilo sele , so fun mi” ni ijapa ba dalohun pe jowo je kin ku ooooo. Aguntan baa bere sini bee, leyin opolopo ebe ijapa so fun aguntan pe kiniun oloola iju,akomo nila lai lo abe ni o gba apo eso lowo oun ati wipe  Ori ni o yo oun ti ko fifi oun see ounje. Aguntan gba won si ni lati pada
Sile be niwon igba ti won ko ti mu ju apo kan lowo wa,ki won si gba fun olorun pe iwonba ti won ba rije nibe ni ere won,won si Kori sile.
     Aguntan gba ona miran pada si igbo opoounje​ lati lo gbe apo ti o toju, ijapa naa see bee geegee.
     Nigba ti won dele, onikaluku,tu apo eso re. ijapa wa ripe okuta at ibaje ni oun gbe wale.o fi ara gbigbona salo si ile aguntan, o ti gbagbe pe oun ti so fun onitoun pe kiniun ti gba eso lo. o ba aguntan ti o n sa eso ti awon ebi re si n je ounje alaadun.
      Ijapa pariwo ” iwo janduku, ole, alagabagebe, bawo no eso se di ibaje ati okuta?” Aguntan bu seerin kakakaka . o so wipe iwo oponu “bawo ni kiniun see wa di ijapa?”.Bayi ni awon ebi aguntan se tii  ijapa Jade kuro ninu ile won ti ijapa si fi ibinu, ibanuje ati ebi pada si ile re.
Eko amulo
1. Ki i se gbogbo eniti a ro pe o go ni ode.
2. Arekereke kii se ogbon.
3. Irele kii se aago
4. Iwa rere daraju iwa arekereke at iwa ole.
5. Eni ti o ba tajajiyepe a gba owo okuta.
 
You may contact ALPHONSO OLASUMBO 
 
CONTACT :
📞 +2348164940200
✉ alphonsoolasumbo@gmail.com
 

written by  © Alphonso Olasumbo, 2017.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *